Yoruba Educational Series

Yoruba Educational Series

Cecilia

Yoruba Educational Series is an initiative of Onasanya Cecilia that Inspires knowledge and experiences through Pedagogical and Andragogical facilitation of the Yoruba Language. She has decades of experiences in teaching the language.

Categories: Education

Listen to the last episode:

LETA AIGBEFE

Leta kiko je ona ti a n gba ranse asiri si ara eni. Ninu leta kiko ni a ti maa n ni anfaani julo lati fi ero ara wa han lori ohunkohun. Yala si ore wa, obi wa, ibatan wa, awon oniwe iroyin, oga ile iwe, ijoba, oga ile ise abbl. 

Ni kukuru LETA AIGBEFE ni leta ti ko gba efe rara. Eyi ni leta  ti a n ko lati wa ise, tabi si ijoba, , ajo gbogbo laarin ilu tabi lawujo tabi nigba ti a ba ni nkan gba lowo awon olu ile ise.

 Ewe, a tun le ko irufe leta bayi si 

 • - Olootu iwe iroyin 
 • - Oga ile iwe
 • - Giwa ile ise abbl.

Igbese inu LETA AIGBEFE

 1. - Adiresi eni ti o n ko leta
 2. - Deeti
 3. - Ipo ati adiresi eni ti a n ko leta si
 4. - Ikini ibere
 5. - Ori oro/Anole
 6. - Inu leta
 7. -Ikini ipari ati Oruko eni ti o ko leta pelu ifowosi

 

Apeere KIKO AIGBEFE

                                                                 2 Oluwaseyi Street, Bariga Lagos. 

2nd June 2021.


Oga Ile Iwe, 

Muslim Junior College, 

 No 13 Alaafia Street, 

Oworonshoki, 

Lagos. 

Sa, 

                                         Itoro aye lati lo fun Odun Ibile

Mo fi asiko yi toro aaye lati lo si ilu mi fun ayeye odun egungun ti a maa n se lodoodun.

  Inu mi a dun bi e ba le gbami laaaye lati kopa ninu odun yii gege bi asa mi lodoodun. 

              Emi ni tiyin

              Rafiu Ajani.

Previous episodes

 • 23 - Leta Aigbefe V2 
  Mon, 31 May 2021
 • 22 - ORISIRI ORUKO ILE YORUBA 
  Tue, 12 Jan 2021
 • 21 - Ise isenbaye ile Yoruba 
  Tue, 12 Jan 2021
 • 20 - IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ORISA 
  Tue, 12 Jan 2021
 • 19 - GHOLOHUN OLOPO ORO ISE 
  Tue, 12 Jan 2021
Show more episodes

More Trinidad education podcasts

More international education podcasts

Choose podcast genre